Ṣé òtítọ́ ni pé a lè fi ewé efinrin fọ kíndìnrín mọ́ láìsí ìrora?

[ad_1]

Àtẹ̀jáde kan lórí ayélujára tí wọ́n pín sí ojú òpó Facebook àti ìkànnì abẹ́yẹfò (Twitter) ló gbé àhesọ kan pé a lè fi ewé efinrin fọ kíndìnrín mọ́.

Àtẹ̀jáde àtijọ́ kan tí wọ́n s’àtúnpín sí orí ìkànnì Facebook ní, “Bi ọdún ṣe ń g’orí ọdún, kíndìnrín àwa ènìyàn máa ń yọ iyọ̀, májèlé àti àwọn oun míràn tí ó lè ṣe aburú fún àgọ́ ara wa kúrò ní ara.”

Àtẹ̀jáde náà gbé àhesọ pé bí ọjọ́ ṣe ń lọ, iyọ̀ á máa kórajọ sí inú kíndìnrín, eléyìí tí ó jẹ́ kí ó pọn dandan fún wa láti máa fọ kíndìnrín wa mọ́.

Ò tún fi kún un wí pé ọ̀nà kàn tí àwọn olùmúlò ojú òpó lè gbà fọ kíndìnrín ni kí wọ́n bọ ewé efinrin, kí wọ́n sì mu omi efinrin tí a ṣẹ ti a yọ ìdọ̀tí rẹ kúrò.

”Mu ife kan lójúmọ́, óò sì ri pé gbogbo iyọ̀ àti májèlé tó ti kórajọ sínú kíndìnrín rẹ yóò jáde pẹ̀lú ìtọ̀ rẹ. Èyí ni ìtọ́jú fún kíndìnrín tó dára jùlọ, àdáyébá sí ni,” báyìí ni àtẹ̀jáde náà wí.

Ocimum gratissimum ni a mọ ewé yìí sí nínú Ìjìnlẹ̀ sáyẹnsì. A tún mọ ewé yìí sí wild basil tàbí igi basil.

Ewé efinrin ni àwọn Yorùbá máa ń pèé, àwọn Ìgbò mọ̀ọ́ si Nchuanwu, àwọn Hausa a sì máa pèé ní Daidoya.

Àtẹ̀jáde lórí ìkànnì ìbáraẹnisọ̀rọ̀ WhatsApp náà gba àwọn olùmúlò ní ìmọ̀ràn pé kí wọ́n s’àtúnpín rẹ̀ sí àwọn ọ̀rẹ́ àti afẹ́nifẹ́re wọn.

Kíndìnrín jẹ́ ìkan lára àwọn ẹ̀yà ara tí ó se pàtàkì. Ó jẹ́ oun tí ó dàbí kóró ẹwa ní ẹgbẹ méjèèjì ọ̀pá ẹ̀hìn, ní abẹ iha ẹ̀gbẹ́.

Iṣẹ́ kíndìnrín ni láti yọ ìdọ̀tí inú ẹ̀jẹ̀ kúrò, àti láti rí wí pé omi ara kò pọju.

Iṣamudaju

TheCable ṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ iṣẹ́ òògùn òyìnbó láti mọ̀ bóyá ẹ̀rí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹnsì ṣe àtìlẹ́yìn lílo ewé efinrin láti fọ kíndìnrín.

Theophilus Umeizudike, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa kíndìnrín (nephrologist) ní ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ ti ilé ìwé gíga ti ìlú Èkó, Lagos State University Teaching Hospital, ní Ikẹja sọ wí pé, “kò sí ẹ̀rí tó dájú pé a lè fi ewé efinrin fọ kíndìnrín mọ́.”

Ó tún gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àmọ̀ràn wí pé kí wọ́n ṣọ́ra fún ìròyìn tí wọ́n pín káàkiri àwọn oun ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ìgbàlódé tàbí orí ayélujára, pàápàá jùlọ èyí tí kò wá láti ilé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ètò ìlera òògùn tí àwọn onímọ̀ tí ó péye fi ọwọ́ sí.

Ó ní, “Ti àwọn ènìyàn bá ka àwọn ǹkan báyìí lórí ayélujára, òun á gbà wọ́n nímọ̀ràn pé kí wọ́n ríi dájú pé ó wá láti ilé ẹ̀kọ́ tó ṣeé gbẹkẹle, kí wọ́n ṣì ríi dájú pé ìmọ̀ sáyẹnsì ṣe àtìlẹ́yìn ọ̀rọ̀ náà àti pé ǹkan ọ̀ún ṣe àǹfààní fún ara.”

Bí a ṣe lè ṣe ìtọ́jú kíndìnrín 

TheCable tún kàn sí Awofẹsọ Ọpẹyẹmi ẹlẹgbẹ ìwádìí ní Harvard Medical School àti Dana-Farber Cancer Institute ní Massachusetts ní ìlú Amerika.

Ó ní kòsí àrídájú nínú ìmọ̀ sáyẹnsì pé a lè fi ewé efinrin fọ kíndìnrín mọ́.

“Ìlera kíndìnrín ò nílò ǹkan púpọ̀,” Ọpẹyẹmi lo sọ báyìí, ó fi kún un wí pé, “tí a bá mu omi déédéé lójoojúmọ́ (lita mẹ́ta tàbí ife méjìlá fún àgbàlagbà), èyí lè dènà àrùn kíndìnrín. Ife omi tí ó mọ́ kan ti tó, ẹ ò nílò láti fi ńkankan kún un.”

Awofẹsọ ní ìlera kíndìnrín kò ju ẹ̀dínkù jíjẹ iyọ̀, mímu ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, àti ṣíṣe ìtọ́jú ẹ̀jẹ̀ ríru. Ó ní àiṣe ìtọ́jú ẹ̀jẹ̀ ríru lè fa àrùn kíndìnrín.

“Ti àyẹ̀wò bá ti ṣàfihàn pé ènìyàn ni àìsàn ẹ̀jẹ̀ ríru, lílo òògùn tó dojúkọ àìsàn yìí, pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà dọ́kítà, ọ̀nà tí ènìyàn yóò fi ní àìlera kíndìnrín yóò dínkù,” Awofẹsọ ló sọ báyìí.

“Ìdí ni pé ẹ̀jẹ̀ ríru kìí farahàn àyàfi tí ẹ̀yà ara bíi kíndìnrín báti bàjẹ́. Ni ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn ẹlòmíràn nígbà tí wọ́n ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, àyẹ̀wò fihàn pé wọ́n ní ẹ̀jẹ̀ ríru, wọ́n sì fún wọn ní òògùn, sùgbọ́n wọn yóò ló fún ìgbà díẹ̀, wọn á sì dá dúró. Yóò wá dàbí ẹni pé kò sí wàhálà kankan títí di ọjọ́ iwájú.”

Àbájáde Ìwádìí 

Irọ́ gbáà ni àhesọ pé ewé efinrin lè fọ kíndìnrín mọ́.

[ad_2]

Source link

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *